Oríkì Ìlú Ẹ̀gbá | Eulogy of Ẹ̀gbá Land | AbalayeTV

Описание к видео Oríkì Ìlú Ẹ̀gbá | Eulogy of Ẹ̀gbá Land | AbalayeTV

Lyrics:
Ẹ̀gbá ọmọ Lísàbí,
Àgbòǹgbò Àkàlà.
Ọmọ erín jogún ọlá,
Ọmọ ò-ṣílẹ̀kùn palẹ̀kùndé.
Arídìí ògo lójú ogun,
Baba tèmi lá a ròyìn ogun Baara f'ágbẹ̀.
Ọmọ ẹni dúdú 'ò sí nílé,
Pupa tó wà nílé 'ò mọbẹ̀ ẹ́ sè.
Kò s'óhun tí wọ́n ń ṣe ní Mẹ́kà,
Táwa kì í ṣe l'Ẹ́gbàá ti wa.
Wọ́n ń mu'mi sẹ́mí-sẹmì ní Mẹ́kà,
Àwa ń mu'mi odò Ògùn l'Ẹ́gbàá.
Wọ́n ń gàràfá ní Mẹ́kà,
Àwa ń g'òkè Olúmọ l'Ẹ́gbàá ti wa.
Ẹ̀gbá ará Aké-màjó,
Ọmọ Màjójó l'Ọ́fà,
Jòjò l'Ọ́fà kunkundin ń j'ẹni.
Ẹ̀yin lọmọ a-jó-gbẹrú, má jò ó gbẹ̀kọ.
Nítorí ẹrú ní ń sin ni.
Ẹ̀kọ kì í sìnnìyàn.
Ọmọ atẹ́ní wíjọ́wíjọ́,
Tí irun rẹ̀ ń gbọ̀n ọ́n lẹ̀ tẹẹrẹrẹ.
Onírúurú Ẹ̀gbá pọ̀ nílé Aláké,
Olúgbọ́njọbí lolórí wọn.
Ìjà kan, ìjà kàn tí wọ́n jà lọjà,
N ló túlùú Ẹ̀gbá Orílé,
N ló sọ Ṣódẹkẹ́ di baba Ogun lábẹ́ Olúmọ.
Ẹ̀gbá ọmọ òru là á ṣè'kà,
Ẹní ṣe'rú rẹ̀ lọ́sàn-án ńkọ́?
Kò ní fara' re lọ.
Ẹ̀gbá méjì kì í jara wọn níyàn,
B'ọ́kan bá ń wí,
Èkejì a sì ní báawà.
Onírúurú Ẹ̀gbá pọ̀ nílé Aláké,
Ẹ̀gbá Àgùrá, Ẹ̀gbá Òwu,
Ẹ̀gbá Òkè-ọnà, Ẹ̀gbá Aláké,
Gbogbo wọn ló gba Ìjàyè lálejò lábẹ́ Olúmọ.
Èdùmàrè jọ̀wọ́ má jẹ̀ ẹ́ k'ílùú Ẹ̀gbá tú o.
Àṣẹ.

ORIN
K'ógun má j'Ẹ̀gbá Aké,
K'ógun má j'Ẹ̀gbá Òwu,
K'ógun má j'Ọsilẹ̀,
K'ógun má j'Àgùrá,
K'ógun má ja'Barà,
Títí d'Ómidá.
Copyright: Abalaye Naijiria

Facebook: www.facebook.com/abalayenigeria
Instagram: www.instagram.com/abalayenigeria
Youtube: AbalayeTV
Twitter: www.twitter.com/abalayenigeria

Комментарии

Информация по комментариям в разработке